35 Nígbà tó rí i, ó fa aṣọ ara rẹ̀ ya, ó sì sọ pé: “Áà, ọmọbìnrin mi! O ti mú kí ọkàn mi bà jẹ́,* torí ìwọ ni ẹni tí màá ní kó lọ. Mo ti la ẹnu mi sí Jèhófà, mi ò sì lè yí i pa dà.”+
24 Àmọ́, ó ti rẹ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tẹnutẹnu ní ọjọ́ yẹn, torí Sọ́ọ̀lù ti mú kí àwọn èèyàn náà búra pé: “Ègún ni fún ẹni tó bá jẹ oúnjẹ* kankan kó tó di ìrọ̀lẹ́ àti kó tó di ìgbà tí màá gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi!” Torí náà, kò sí ẹnì kankan nínú àwọn èèyàn náà tí ó fi oúnjẹ kan ẹnu.+