18 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà bá Ábúrámù dá májẹ̀mú+ kan pé: “Ọmọ* rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí,+ láti odò Íjíbítì dé odò ńlá náà, ìyẹn odò Yúfírétì:+19 ilẹ̀ àwọn Kénì,+ àwọn ọmọ Kénásì, àwọn Kádímónì, 20 àwọn ọmọ Hétì,+ àwọn Pérísì,+ àwọn Réfáímù,+
11 Ógù ọba Báṣánì ló ṣẹ́ kù nínú àwọn Réfáímù. Irin* ni wọ́n fi ṣe àga ìgbókùú* rẹ̀, ó ṣì wà ní Rábà ti àwọn ọmọ Ámónì. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* mẹ́sàn-án, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, wọ́n lo ìgbọ̀nwọ́ tó péye.