18 “‘Màá fi idà,+ ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn lé wọn, màá sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù lójú gbogbo ìjọba ayé,+ màá sì sọ wọ́n di ẹni ègún àti ohun ìyàlẹ́nu, ohun àrísúfèé+ àti ẹni ẹ̀gàn láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí màá fọ́n wọn ká sí,+
24 Wọ́n máa fi ojú idà ṣá wọn balẹ̀, wọ́n á sì kó wọn lẹ́rú lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè;+ àwọn orílẹ̀-èdè* sì máa tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀, títí àkókò tí a yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè* fi máa pé.+