12 Nígbà yẹn, a gba ilẹ̀ yìí: láti Áróérì,+ èyí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Àfonífojì Áánónì àti ìdajì agbègbè olókè Gílíádì, mo sì ti fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì+ ní àwọn ìlú rẹ̀.
47 Wọ́n sì gba ilẹ̀ rẹ̀ àti ilẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì, àwọn ọba Ámórì méjèèjì, tí wọ́n wà ní agbègbè tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, 48 láti Áróérì,+ èyí tó wà létí Àfonífojì Áánónì, títí dé Òkè Síónì, ìyẹn Hámónì,+
8 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà tó kù, wá gba ogún wọn tí Mósè fún wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe fún wọn:+9 láti Áróérì,+ tó wà létí Àfonífojì Áánónì+ àti ìlú tó wà láàárín àfonífojì náà àti gbogbo ilẹ̀ tó tẹ́jú* ní Médébà títí dé Díbónì;