-
Ẹ́kísódù 23:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Torí áńgẹ́lì mi yóò ṣáájú yín, yóò sì mú yín wá sọ́dọ̀ àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì, màá sì pa wọ́n run.+
-
-
Nọ́ńbà 22:23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí áńgẹ́lì Jèhófà tó dúró sójú ọ̀nà, tó ti fa idà yọ, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fẹ́ yà kúrò lọ́nà kó lè gba inú igbó. Àmọ́ Báláámù bẹ̀rẹ̀ sí í lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà kó lè dá a pa dà sójú ọ̀nà.
-