-
Jóṣúà 2:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ní báyìí, ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi Jèhófà búra fún mi pé ẹ̀yin náà máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí agbo ilé bàbá mi, torí mo ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí yín; kí ẹ fún mi ní àmì kan tó ṣeé gbára lé.* 13 Kí ẹ dá ẹ̀mí bàbá mi àti ìyá mi sí, àwọn arákùnrin mi àtàwọn arábìnrin mi àti gbogbo èèyàn wọn, kí ẹ sì gbà wá* lọ́wọ́ ikú.”+
-
-
Jóṣúà 2:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Àwọn ọkùnrin náà sọ fún un pé: “A ò ní jẹ̀bi ìbúra tí o mú ká ṣe yìí+ 18 àfi tí a bá dé ilẹ̀ yìí, tí o sì ti so okùn aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí mọ́ ojú fèrèsé tí o gbà sọ̀ wá kalẹ̀. Kí o mú bàbá rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin rẹ àti gbogbo agbo ilé bàbá rẹ wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ilé.+ 19 Tí ẹnikẹ́ni bá wá kúrò nínú ilé rẹ, tó sì jáde sí ìta, òun fúnra rẹ̀ ló máa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀bi náà ò ní sí lọ́rùn wa. Àmọ́ tí aburú bá ṣe* ẹnikẹ́ni tó wà nínú ilé lọ́dọ̀ rẹ, ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ máa wà lọ́rùn wa.
-