21 Nígbà tí mo rí ẹ̀wù oyè kan tó rẹwà láti Ṣínárì+ láàárín àwọn ẹrù ogun àti igba (200) ṣékélì fàdákà àti wúrà gbọọrọ kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì, ọkàn mi fà sí i, mo sì kó o. Abẹ́ ilẹ̀ nínú àgọ́ mi ni mo kó o pa mọ́ sí, mo sì kó owó náà sábẹ́ rẹ̀.”