9“Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, ò ń sọdá Jọ́dánì lónìí,+ láti wọ ilẹ̀ náà kí o lè lọ lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ kúrò,+ àwọn ìlú tó tóbi, tí wọ́n sì mọ odi rẹ̀ kan ọ̀run,*+
2 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, àwọn olórí+ lọ káàkiri ibùdó, 3 wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà pé: “Gbàrà tí ẹ bá rí i tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà+ gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ gbéra láti àyè yín, kí ẹ sì tẹ̀ lé e.