-
Diutarónómì 3:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Àwọn ìyàwó yín àti àwọn ọmọ yín nìkan ni yóò máa gbé inú àwọn ìlú tí mo fún yín, títí kan àwọn ẹran ọ̀sìn yín (mo mọ̀ dáadáa pé ẹ ní ẹran ọ̀sìn tó pọ̀), 20 títí Jèhófà fi máa fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi, bíi tiyín, tí wọ́n á sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín máa fún wọn ní òdìkejì Jọ́dánì. Lẹ́yìn náà, kí kálukú yín pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀ tí mo fún yín.’+
-
-
Diutarónómì 29:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Lẹ́yìn náà, a gba ilẹ̀ wọn, a sì fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè+ pé kó jẹ́ ogún tiwọn.
-
-
Jóṣúà 13:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà tó kù, wá gba ogún wọn tí Mósè fún wọn lápá ìlà oòrùn Jọ́dánì, bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe fún wọn:+
-