-
Diutarónómì 20:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ dá ohun eléèémí kankan sí ní ìlú àwọn èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún.+ 17 Ṣe ni kí o pa wọ́n run pátápátá, ìyẹn àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́; 18 kí wọ́n má bàa kọ́ yín láti máa ṣe gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kí wọ́n wá mú kí ẹ ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín.+
-