-
Jóṣúà 18:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Ààlà náà tún lọ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá àríwá Bẹti-hógílà,+ ó sì parí sí ibi tí omi ti ya wọ ilẹ̀ lápá àríwá Òkun Iyọ̀,*+ ní ìpẹ̀kun Jọ́dánì lápá gúúsù. Èyí ni ààlà náà lápá gúúsù. 20 Jọ́dánì sì ni ààlà rẹ̀ lápá ìlà oòrùn. Èyí ni ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ààlà rẹ̀ yí ká.
-