38 Níkẹyìn, Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì ṣẹ́rí pa dà, wọ́n sì lọ bá Débírì+ jà. 39 Ó gba ibẹ̀, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú rẹ̀, wọ́n sì fi idà pa wọ́n, wọ́n pa gbogbo àwọn tó ń gbé ibẹ̀ run,+ wọn ò ṣẹ́ ẹnì kankan kù.+ Ohun tó ṣe sí Hébúrónì àti Líbínà àti ọba rẹ̀ náà ló ṣe sí Débírì àti ọba rẹ̀.