-
Àwọn Onídàájọ́ 3:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,+ Jèhófà yan ẹnì kan tó máa gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀,+ ìyẹn Ótíníẹ́lì+ ọmọ Kénásì, àbúrò Kélẹ́bù. 10 Ẹ̀mí Jèhófà bà lé e,+ ó sì di onídàájọ́ Ísírẹ́lì. Nígbà tó lọ jagun, Jèhófà fi Kuṣani-ríṣátáímù ọba Mesopotámíà* lé e lọ́wọ́, ó sì ṣẹ́gun Kuṣani-ríṣátáímù. 11 Àlàáfíà wá wà ní ilẹ̀ náà* fún ogójì (40) ọdún. Lẹ́yìn náà, Ótíníẹ́lì ọmọ Kénásì wá kú.
-