12 Ó fèsì pé: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ,+ ohun tí yóò sì jẹ́ àmì fún ọ pé èmi ni mo rán ọ nìyí: Lẹ́yìn tí o bá ti mú àwọn èèyàn náà kúrò ní Íjíbítì, ẹ máa jọ́sìn* Ọlọ́run tòótọ́ lórí òkè yìí.”+
31 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún rí agbára* ńlá tí Jèhófà fi bá àwọn ará Íjíbítì jà, àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù Jèhófà, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀.+