52 Kí ẹ lé gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, kí ẹ run gbogbo ère tí wọ́n fi òkúta+ ṣe àti gbogbo ère onírin*+ wọn, kí ẹ sì wó gbogbo ibi gíga+ tí wọ́n ti ń jọ́sìn àwọn òrìṣà.
55 “‘Àmọ́ tí ẹ ò bá lé àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín,+ àwọn tí ẹ bá fi sílẹ̀ lára wọn máa dà bí ohun ìríra lójú yín, wọ́n á dà bí ẹ̀gún tó ń gún yín lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n á sì máa yọ yín lẹ́nu ní ilẹ̀ tí ẹ máa gbé.+