2Jóṣúà ọmọ Núnì wá rán ọkùnrin méjì jáde ní bòókẹ́lẹ́ láti Ṣítímù,+ pé kí wọ́n lọ ṣe amí. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ yẹ ilẹ̀ náà wò, pàápàá ilẹ̀ Jẹ́ríkò.” Torí náà, wọ́n lọ, wọ́n dé ilé aṣẹ́wó kan tó ń jẹ́ Ráhábù,+ wọ́n sì dúró sí ibẹ̀.
16Ilẹ̀ tí wọ́n fi kèké pín*+ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù+ bẹ̀rẹ̀ láti Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò dé ibi omi tó wà lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, ó gba inú aginjù láti Jẹ́ríkò lọ sí agbègbè olókè Bẹ́tẹ́lì.+