14 Kí ẹ yan ìlú mẹ́ta ní apá ibí yìí ní Jọ́dánì,+ kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ilẹ̀ Kénáánì+ láti fi ṣe ìlú ààbò. 15 Ìlú mẹ́fà yìí máa jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àjèjì+ àtàwọn tí wọ́n jọ ń gbé, ibẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tó bá ṣèèṣì pa èèyàn+ máa sá wọ̀.