3 kí o sì pàṣẹ fún wọn pé: ‘Ẹ gbé òkúta méjìlá (12) ní àárín Jọ́dánì, níbi tí ẹsẹ̀ àwọn àlùfáà tó dúró sójú kan wà,+ kí ẹ gbé àwọn òkúta náà dání, kí ẹ sì tò wọ́n síbi tí ẹ máa sùn mọ́jú.’”+
6 Àwọn ará Gíbíónì wá ránṣẹ́ sí Jóṣúà ní ibùdó tó wà ní Gílígálì+ pé: “Má fi àwa ẹrú rẹ sílẹ̀.*+ Tètè máa bọ̀! Wá gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́! Gbogbo àwọn ọba Ámórì láti agbègbè olókè ti kóra jọ láti bá wa jà.”