-
Diutarónómì 31:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ẹ kó àwọn èèyàn náà jọ,+ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé* àti àwọn àjèjì yín tó ń gbé nínú àwọn ìlú* yín, kí wọ́n lè fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n máa bẹ̀rù rẹ̀, kí wọ́n sì lè máa rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí. 13 Àwọn ọmọ wọn tí kò tíì mọ Òfin yìí á wá fetí sílẹ̀,+ wọ́n á sì kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ bá fi wà lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì lọ gbà.”+
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 2:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Àwọn èèyàn náà ṣì ń sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ ayé àwọn àgbààgbà tí ẹ̀mí wọn gùn ju ti Jóṣúà lọ, tí wọ́n sì ti rí gbogbo ohun tó kàmàmà tí Jèhófà ṣe nítorí Ísírẹ́lì.+
-