-
Jẹ́nẹ́sísì 17:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ọlọ́run tún sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní tìrẹ, kí o pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ jálẹ̀ àwọn ìran wọn. 10 Májẹ̀mú tí mo bá ọ dá nìyí, òun sì ni ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò máa pa mọ́: Gbogbo ọkùnrin tó wà láàárín yín gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́.*+ 11 Kí ẹ dá adọ̀dọ́ yín,* yóò sì jẹ́ àmì májẹ̀mú tó wà láàárín èmi àti ẹ̀yin.+
-