14 Jèhófà sọ fún Ábúrámù lẹ́yìn tí Lọ́ọ̀tì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́ gbójú sókè níbi tí o wà, kí o sì wo àríwá àti gúúsù, ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, 15 torí gbogbo ilẹ̀ tí o rí yìí ni màá fún ìwọ àti ọmọ* rẹ, yóò sì di ohun ìní yín títí láé.+
33Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: “Kúrò níbí pẹ̀lú àwọn èèyàn tí o mú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. Kí ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo búra nípa rẹ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé, ‘Ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ ni màá fún.’+