-
Nọ́ńbà 27:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Á sì máa dúró níwájú àlùfáà Élíásárì, ẹni tí yóò máa bá a ṣe ìwádìí níwájú Jèhófà nípasẹ̀ ohun tí Úrímù+ bá sọ. Àṣẹ rẹ̀ ni wọ́n á máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń jáde, àṣẹ rẹ̀ ni wọ́n á sì máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń wọlé, òun àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú gbogbo àpéjọ náà.”
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 20:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Wọ́n gbéra, wọ́n sì lọ sí Bẹ́tẹ́lì láti wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run.+ Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì wá sọ pé: “Ta ni kó ṣáájú nínú wa láti lọ bá àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì jà?” Jèhófà fèsì pé: “Júdà ni kó ṣáájú.”
-