1Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí àwọn onídàájọ́+ ń ṣe àbójútó* ní Ísírẹ́lì, ìyàn mú ní ilẹ̀ náà. Ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì kúrò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà, wọ́n sì lọ ń gbé ní ilẹ̀* Móábù.+
6 Òun àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ wá gbéra, wọ́n sì fi ilẹ̀ Móábù sílẹ̀, torí ó ti gbọ́ ní Móábù pé Jèhófà ti ṣíjú àánú wo àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ti ń fún wọn ní oúnjẹ.*