-
Rúùtù 1:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
1 Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí àwọn onídàájọ́+ ń ṣe àbójútó* ní Ísírẹ́lì, ìyàn mú ní ilẹ̀ náà. Ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì kúrò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ní Júdà, wọ́n sì lọ ń gbé ní ilẹ̀* Móábù.+ 2 Élímélékì* ni orúkọ ọkùnrin náà, Náómì* ni orúkọ ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ń jẹ́ Málónì* àti Kílíónì.* Ará Éfúrátà ni wọ́n, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó wà ní Júdà. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Móábù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀.
-