-
1 Sámúẹ́lì 6:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Wọ́n fèsì pé: “Bí ẹ bá máa dá àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì pa dà, ẹ má ṣe dá a pa dà láìsí ọrẹ. Ẹ gbọ́dọ̀ dá a pa dà pẹ̀lú ọrẹ ẹ̀bi.+ Ìgbà yẹn ni ara yín máa tó yá, tí ẹ sì máa mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ ṣì fi le mọ́ yín.” 4 Ni wọ́n bá béèrè pé: “Ọrẹ ẹ̀bi wo ni ká fi ránṣẹ́ sí i?” Wọ́n sọ pé: “Ẹ fi jẹ̀díjẹ̀dí* wúrà márùn-ún àti eku wúrà márùn-ún ránṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn alákòóso Filísínì,+ nítorí irú àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọ lu ẹnì kọ̀ọ̀kan yín àti àwọn alákòóso yín.
-