4 Ni wọ́n bá béèrè pé: “Ọrẹ ẹ̀bi wo ni ká fi ránṣẹ́ sí i?” Wọ́n sọ pé: “Ẹ fi jẹ̀díjẹ̀dí wúrà márùn-ún àti eku wúrà márùn-ún ránṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn alákòóso Filísínì,+ nítorí irú àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọ lu ẹnì kọ̀ọ̀kan yín àti àwọn alákòóso yín.