3 wọ́n ránṣẹ́ pè é. Lẹ́yìn náà, Jèróbóámù àti gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì wá bá Rèhóbóámù, wọ́n sì sọ pé: 4 “Bàbá rẹ mú kí àjàgà wa wúwo.+ Àmọ́ tí o bá mú kí iṣẹ́ tó nira tí bàbá rẹ fún wa rọ̀ wá lọ́rùn, tí o sì mú kí àjàgà tó wúwo tó fi kọ́ wa lọ́rùn fúyẹ́, a ó máa sìn ọ́.”