-
Àwọn Onídàájọ́ 21:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Wọ́n béèrè pé: “Èwo nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni kò wá sọ́dọ̀ Jèhófà ní Mísípà?”+ Ó ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kankan ò wá láti Jabeṣi-gílíádì sínú ibùdó tí ìjọ náà wà.
-
-
1 Sámúẹ́lì 31:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Nígbà tí àwọn tó ń gbé ní Jabeṣi-gílíádì+ gbọ́ ohun tí àwọn Filísínì ṣe sí Sọ́ọ̀lù, 12 gbogbo àwọn jagunjagun gbéra, wọ́n sì rìnrìn àjò ní gbogbo òru, wọ́n gbé òkú Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lára ògiri Bẹti-ṣánì. Wọ́n pa dà sí Jábéṣì, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀.
-