-
1 Sámúẹ́lì 9:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 “Ní ìwòyí ọ̀la, màá rán ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì sí ọ.+ Kí o fòróró yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì,+ yóò sì gba àwọn èèyàn mi lọ́wọ́ àwọn Filísínì. Nítorí mo ti rí ìpọ́njú àwọn èèyàn mi, igbe ẹkún wọn sì ti dé ọ̀dọ̀ mi.”+ 17 Nígbà tí Sámúẹ́lì rí Sọ́ọ̀lù, Jèhófà sọ fún un pé: “Ọkùnrin tí mo sọ nípa rẹ̀ fún ọ nìyí pé, ‘Òun ló máa ṣàkóso àwọn èèyàn mi.’”*+
-
-
1 Sámúẹ́lì 10:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ṣé ẹ rí ẹni tí Jèhófà yàn,+ pé kò sí ẹnì kankan tó dà bíi rẹ̀ láàárín gbogbo èèyàn?” Gbogbo àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!”
-