2 Sọ́ọ̀lù yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn látinú Ísírẹ́lì; ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) lára wọn wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù ní Míkímáṣì àti ní agbègbè olókè Bẹ́tẹ́lì, ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà pẹ̀lú Jónátánì+ ní Gíbíà+ ti Bẹ́ńjámínì. Ó rán ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn náà lọ sí àgọ́ wọn.