-
1 Sámúẹ́lì 17:38, 39Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 Sọ́ọ̀lù wá gbé ẹ̀wù rẹ̀ wọ Dáfídì. Ó fi akoto* bàbà dé e lórí, lẹ́yìn náà ó gbé ẹ̀wù irin wọ̀ ọ́. 39 Dáfídì sì di idà rẹ̀ mọ́ ẹ̀wù rẹ̀, ó fẹ́ máa lọ, àmọ́ kò lè rìn, nítorí kò mọ́ ọn lára. Ni Dáfídì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Mi ò lè wọ nǹkan wọ̀nyí rìn, nítorí wọn ò mọ́ mi lára.” Torí náà, Dáfídì bọ́ wọn kúrò.
-