17 Ìgbà náà ni Jésè sọ fún Dáfídì ọmọ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, gba àyangbẹ ọkà òṣùwọ̀n eéfà yìí àti búrẹ́dì mẹ́wàá yìí, kí o tètè gbé e lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ní ibùdó. 18 Gba wàrà mẹ́wàá yìí lọ fún olórí ẹgbẹ̀rún; bákan náà, kí o wo àlàáfíà àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, kí o sì gba àmì ìdánilójú bọ̀ látọ̀dọ̀ wọn.”