9 Jèhófà jẹ́ kí ẹ̀mí búburú mú Sọ́ọ̀lù+ nígbà tó jókòó nínú ilé rẹ̀, tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì wà lọ́wọ́ rẹ̀, bí Dáfídì ṣe ń fi háàpù+ kọrin lọ́wọ́. 10 Sọ́ọ̀lù fẹ́ fi ọ̀kọ̀ gún Dáfídì mọ́ ògiri, àmọ́ ó yẹ ọ̀kọ̀ Sọ́ọ̀lù, ọ̀kọ̀ náà sì wọnú ògiri. Dáfídì sì sá lọ ní òru ọjọ́ yẹn.