-
Léfítíkù 24:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Kí o fi ògidì oje igi tùràrí sórí ìpele kọ̀ọ̀kan, yóò sì jẹ́ búrẹ́dì ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ*+ tó jẹ́ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 8 Kó máa tò ó síwájú Jèhófà nígbà gbogbo+ ní ọjọ́ Sábáàtì kọ̀ọ̀kan. Májẹ̀mú tí mo bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ni, ó sì máa wà títí lọ. 9 Yóò di ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ wọ́n á sì jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́,+ torí ó jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ fún un látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, ìlànà tó máa wà títí lọ ni.”
-
-
Máàkù 2:25, 26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe rí ni, nígbà tó ṣaláìní, tí ebi sì ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+ 26 Nínú ìtàn Ábíátárì+ olórí àlùfáà, bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tó sì jẹ àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,* èyí tí kò bófin mu fún ẹnikẹ́ni láti jẹ àfi àwọn àlùfáà,+ tó sì tún fún àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ lára rẹ̀?”
-
-
Lúùkù 6:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Àmọ́ Jésù fún wọn lésì pé: “Ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe rí ni, nígbà tí ebi ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀?+ 4 Bó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tó gba àwọn búrẹ́dì tí wọ́n ń gbé síwájú,* tó sì jẹ ẹ́, tó tún fún àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ, èyí tí kò bófin mu fún ẹnì kankan láti jẹ, àfi àwọn àlùfáà nìkan?”+
-