-
1 Sámúẹ́lì 21:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Nígbà tó yá, Dáfídì wá sọ́dọ̀ àlùfáà Áhímélékì ní Nóbù.+ Jìnnìjìnnì bá Áhímélékì nígbà tó pàdé Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi dá wá, tí kò sẹ́ni tó tẹ̀ lé ọ?”+ 2 Dáfídì dá àlùfáà Áhímélékì lóhùn pé: “Ọba ní kí n ṣe ohun kan, àmọ́ ó sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ohunkóhun nípa iṣẹ́ tí mo rán ọ àti àṣẹ tí mo pa fún ọ.’ Torí náà, mo bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ṣe àdéhùn pé ká pàdé níbì kan.
-