-
1 Sámúẹ́lì 22:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Nítorí náà, Dáfídì kúrò níbẹ̀,+ ó sì sá lọ sí ihò Ádúlámù.+ Nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àti gbogbo ilé bàbá rẹ̀ gbọ́, wọ́n lọ bá a níbẹ̀. 2 Gbogbo àwọn tó wà nínú wàhálà, àwọn tó jẹ gbèsè àti àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn* kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì di olórí wọn. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin ló wà pẹ̀lú rẹ̀.
-
-
1 Sámúẹ́lì 25:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Lójú ẹsẹ̀, Dáfídì sọ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Kí kálukú yín sán idà rẹ̀!”+ Nítorí náà, gbogbo wọn sán idà wọn, Dáfídì náà sán idà rẹ̀, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin sì tẹ̀ lé Dáfídì, nígbà tí igba (200) ọkùnrin jókòó ti ẹrù wọn.
-
-
1 Sámúẹ́lì 30:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ní kíá, Dáfídì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin+ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ gbéra, wọ́n sì lọ títí dé Àfonífojì Bésórì, ibẹ̀ ni àwọn kan lára wọn dúró sí.
-