18 Sámúẹ́lì sì ń ṣe ìránṣẹ́+ níwájú Jèhófà, ó wọ éfódì tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀+ ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọdékùnrin ni. 19 Bákan náà, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ àwọ̀lékè kékeré tí kò lápá fún un, a sì mú un wá fún un lọ́dọọdún nígbà tí òun àti ọkọ rẹ̀ bá wá láti rú ẹbọ ọdọọdún.+