19 Àwọn kan lára ẹ̀yà Mánásè náà sá wá sọ́dọ̀ Dáfídì nígbà tó tẹ̀ lé àwọn Filísínì láti wá bá Sọ́ọ̀lù jà. Àmọ́ kò lè ran àwọn Filísínì lọ́wọ́, torí lẹ́yìn tí wọ́n gbàmọ̀ràn, àwọn alákòóso Filísínì+ ní kó pa dà, wọ́n ní: “Ó máa sá lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù olúwa rẹ̀, ẹ̀mí wa ló sì máa lọ sí i.”+