-
1 Sámúẹ́lì 27:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Dáfídì kì í dá ọkùnrin tàbí obìnrin kankan sí tó máa mú wá sí Gátì, á sọ pé: “Kí wọ́n má bàa rojọ́ wa fún wọn pé, ‘Ohun tí Dáfídì ṣe nìyí.’” (Bí ó sì ṣe máa ń ṣe nìyẹn ní gbogbo ìgbà tó fi ń gbé ní ìgbèríko àwọn Filísínì.) 12 Nítorí náà, Ákíṣì gba Dáfídì gbọ́, ó sì ń sọ fún ara rẹ̀ pé: ‘Ó dájú pé ó ti di ẹni ìkórìíra láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì, torí náà, á máa jẹ́ ìránṣẹ́ mi títí lọ.’
-