7 Nígbà náà, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibi ààbò, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Ìlú Dáfídì. 8 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìlú náà yí ká láti Òkìtì títí dé àyíká rẹ̀, Jóábù sì tún apá tó kù lára ìlú náà kọ́. 9 Bí agbára Dáfídì ṣe ń pọ̀ sí i+ nìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀.