14 Hírámù+ ọba Tírè rán àwọn òjíṣẹ́ sí Dáfídì, ó kó igi kédárì ránṣẹ́, ó tún rán àwọn oníṣẹ́ òkúta àti àwọn oníṣẹ́ igi láti kọ́ ilé fún un.+ 2 Dáfídì wá mọ̀ pé Jèhófà ti fìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì,+ torí pé Ó ti gbé ìjọba Dáfídì ga nítorí àwọn èèyàn Rẹ̀ Ísírẹ́lì.+