ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 15:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Ààlà náà dé Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ ààlà náà dé orí òkè tó dojú kọ Àfonífojì Hínómù lápá ìwọ̀ oòrùn, èyí tó wà ní ìkángun Àfonífojì* Réfáímù lápá àríwá.

  • Jóṣúà 15:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Ààlà náà lápá ìwọ̀ oòrùn ni Òkun Ńlá*+ àti èbúté rẹ̀. Èyí ni ààlà àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà ní ìdílé-ìdílé yí ká.

  • 1 Kíróníkà 11:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Mẹ́ta lára ọgbọ̀n (30) ọkùnrin tó jẹ́ olórí lọ sí ibi àpáta lọ́dọ̀ Dáfídì ní ihò àpáta Ádúlámù,+ lákòókò yìí, àwùjọ àwọn ọmọ ogun Filísínì kan pàgọ́ sí Àfonífojì* Réfáímù.+

  • 1 Kíróníkà 14:13-17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Nígbà tó yá, àwọn Filísínì tún wá kó nǹkan àwọn èèyàn ní àfonífojì*+ náà. 14 Dáfídì tún wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un pé: “Má ṣe dojú kọ wọ́n ní tààràtà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yìn ni kí o gbà yọ sí wọn, kí o sì wá dojú kọ wọ́n níwájú àwọn igi bákà.+ 15 Tí o bá ti gbọ́ ìró tó ń dún bí ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi bákà, kí o dojú ìjà kọ wọ́n, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ yóò ti lọ ṣáájú rẹ láti ṣá àwọn ọmọ ogun Filísínì balẹ̀.”+ 16 Torí náà, Dáfídì ṣe ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́,+ wọ́n sì pa àwọn ọmọ ogun Filísínì láti Gíbíónì títí dé Gésérì.+ 17 Òkìkí Dáfídì kàn dé gbogbo àwọn ilẹ̀ náà, Jèhófà sì mú kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa bẹ̀rù rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́