-
1 Àwọn Ọba 5:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 “O mọ̀ dáadáa pé Dáfídì bàbá mi kò lè kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ nítorí ogun tí wọ́n fi yí i ká, títí Jèhófà fi fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.+
-
-
1 Kíróníkà 17:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “Lọ sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ìwọ kọ́ ló máa kọ́ ilé tí màá gbé fún mi.+ 5 Nítorí mi ò gbé inú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Ísírẹ́lì jáde títí di òní yìí, àmọ́ mò ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti látinú àgọ́ ìjọsìn kan dé òmíràn.*+ 6 Ní gbogbo àkókò tí mò ń bá gbogbo Ísírẹ́lì rìn, ṣé mo fìgbà kankan sọ fún ọ̀kan lára àwọn onídàájọ́ tí mo yàn láti máa bójú tó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí àgùntàn, pé, ‘Kí ló dé tí ẹ ò fi kọ́ ilé onígi kédárì fún mi?’”’
-