-
1 Kíróníkà 17:16-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ni Ọba Dáfídì bá wọlé, ó jókòó níwájú Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run, ta ni mí? Kí ni ilé mi sì já mọ́ tí o fi mú mi dé ibi tí mo dé yìí?+ 17 Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, ìwọ Ọlọ́run, o tún sọ nípa ilé ìránṣẹ́ rẹ títí lọ dé ọjọ́ iwájú tó jìnnà,+ o sì ṣíjú wò mí bíi pé ẹni tó yẹ ká túbọ̀ gbé ga* ni mí, Jèhófà Ọlọ́run. 18 Kí ni Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ tún lè sọ fún ọ nípa bí o ṣe bọlá fún mi, nígbà tí o sì mọ ìránṣẹ́ rẹ dáadáa?+ 19 Jèhófà, nítorí ìránṣẹ́ rẹ àti nítorí ohun tó wà lọ́kàn rẹ* ni o fi ṣe gbogbo àwọn ohun ńlá yìí, tí o sì tipa bẹ́ẹ̀ fi títóbi rẹ+ hàn. 20 Jèhófà, kò sí ẹni tó dà bí rẹ,+ kò sì sí Ọlọ́run kankan àfi ìwọ;+ gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́ jẹ́rìí sí i. 21 Orílẹ̀-èdè wo ní gbogbo ayé ló dà bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì?+ Ọlọ́run tòótọ́ lọ rà wọ́n pa dà nítorí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀.+ O ṣe orúkọ fún ara rẹ bí o ṣe ń ṣe àwọn ohun ńlá àti àwọn ohun àgbàyanu,+ tí o sì ń lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn èèyàn rẹ+ tí o rà pa dà láti Íjíbítì. 22 O sọ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì di àwọn èèyàn tí á máa jẹ́ tìrẹ títí lọ;+ ìwọ Jèhófà sì di Ọlọ́run wọn.+
-