22 Ó fèsì pé: “Nígbà tí ọmọ náà ṣì wà láàyè, mo gbààwẹ̀,+ mo sì ń sunkún torí mo sọ fún ara mi pé, ‘Ta ló mọ̀ bóyá Jèhófà lè ṣojú rere sí mi, kó sì jẹ́ kí ọmọ náà yè?’+
8 Kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, èèyàn àti ẹran; kí wọ́n ké pe Ọlọ́run tọkàntọkàn, kí wọ́n yí ìwà burúkú wọn pa dà, kí wọ́n sì jáwọ́ nínú ìwà ipá. 9 Ta ló mọ̀ bóyá Ọlọ́run tòótọ́ máa pèrò dà* nípa ohun tó ní lọ́kàn, kó sì yí ìbínú rẹ̀ pa dà, ká má bàa ṣègbé?”