11 Ógù ọba Báṣánì ló ṣẹ́ kù nínú àwọn Réfáímù. Irin* ni wọ́n fi ṣe àga ìgbókùú* rẹ̀, ó ṣì wà ní Rábà ti àwọn ọmọ Ámónì. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* mẹ́sàn-án, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, wọ́n lo ìgbọ̀nwọ́ tó péye.
24 Bákan náà, Mósè pín ogún fún ẹ̀yà Gádì, àwọn ọmọ Gádì ní ìdílé-ìdílé, 25 ara ilẹ̀ wọn sì ni Jásérì+ àti gbogbo ìlú tó wà ní Gílíádì pẹ̀lú ìdajì ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámónì+ títí dé Áróérì, èyí tó dojú kọ Rábà;+