16 Ilẹ̀ tí wọ́n fi kèké pín+ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù+ bẹ̀rẹ̀ láti Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò dé ibi omi tó wà lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, ó gba inú aginjù láti Jẹ́ríkò lọ sí agbègbè olókè Bẹ́tẹ́lì.+ 2 Ó lọ láti Bẹ́tẹ́lì tó jẹ́ ti Lúsì títí dé ààlà àwọn Áríkì ní Átárótì,