ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 1:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Àwọn agbẹ̀bí náà sọ fún Fáráò pé: “Àwọn obìnrin Hébérù ò dà bí àwọn obìnrin Íjíbítì. Wọ́n lágbára, wọ́n sì ti máa ń bímọ kí agbẹ̀bí tó dé ọ̀dọ̀ wọn.”

  • Jóṣúà 2:3-5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Ni ọba Jẹ́ríkò bá ránṣẹ́ sí Ráhábù pé: “Mú àwọn ọkùnrin tó wá síbí jáde, àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, torí ṣe ni wọ́n wá ṣe amí gbogbo ilẹ̀ yìí.”

      4 Àmọ́ obìnrin náà mú àwọn ọkùnrin méjèèjì, ó sì fi wọ́n pa mọ́. Ó wá sọ pé: “Òótọ́ ni àwọn ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ mi, àmọ́ mi ò mọ ibi tí wọ́n ti wá. 5 Nígbà tí ilẹ̀ sì ṣú, tó kù díẹ̀ kí wọ́n ti ẹnubodè ìlú ni àwọn ọkùnrin náà jáde. Mi ò mọ ibi tí àwọn ọkùnrin náà lọ, àmọ́ tí ẹ bá tètè sá tẹ̀ lé wọn, ẹ máa bá wọn.”

  • 1 Sámúẹ́lì 19:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Míkálì sọ Dáfídì kalẹ̀ gba ojú fèrèsé,* kí ó lè sá àsálà.

  • 1 Sámúẹ́lì 19:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Sọ́ọ̀lù wá rán àwọn òjíṣẹ́ láti mú Dáfídì, àmọ́ Míkálì sọ pé: “Ara rẹ̀ ò yá.”

  • 1 Sámúẹ́lì 21:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Dáfídì dá àlùfáà Áhímélékì lóhùn pé: “Ọba ní kí n ṣe ohun kan, àmọ́ ó sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ohunkóhun nípa iṣẹ́ tí mo rán ọ àti àṣẹ tí mo pa fún ọ.’ Torí náà, mo bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ṣe àdéhùn pé ká pàdé níbì kan.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́