ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 31:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi ní àgúnyọ, kí àwọn aláìdádọ̀dọ́*+ yìí má bàa wá gún mi ní àgúnyọ, kí wọ́n sì hùwà ìkà sí mi.”* Àmọ́, ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ẹ̀rù bà á gan-an. Torí náà, Sọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lé e.+

  • 1 Àwọn Ọba 16:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Nígbà tí Símírì rí i pé wọ́n ti gba ìlú náà, ó wọ inú ilé gogoro tó láàbò tó wà ní ilé* ọba, ó dáná sun ilé náà mọ́ ara rẹ̀ lórí, ó sì kú.+

  • Sáàmù 5:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Àmọ́ Ọlọ́run á dá wọn lẹ́bi;

      Èrò ibi wọn á mú kí wọ́n ṣubú.+

      Kí a lé wọn dà nù torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn tó pọ̀ gan-an,

      Nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.

  • Sáàmù 55:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Àmọ́ ìwọ, Ọlọ́run, yóò rẹ̀ wọ́n wálẹ̀ sínú kòtò tó jìn jù lọ.+

      Àwọn tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́tàn kò ní lo ààbọ̀ ọjọ́ ayé wọn.+

      Àmọ́ ní tèmi, màá gbẹ́kẹ̀ lé ọ.

  • Mátíù 27:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Nígbà tí Júdásì, ẹni tó dà á, rí i pé wọ́n ti dá Jésù lẹ́bi, ẹ̀dùn ọkàn bá a, ó sì kó ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà náà pa dà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà,+

  • Mátíù 27:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Torí náà, ó da àwọn ẹyọ fàdákà náà sínú tẹ́ńpìlì, ó sì kúrò níbẹ̀. Ó wá lọ pokùn so.+

  • Ìṣe 1:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 (Ọkùnrin yìí fi owó iṣẹ́ ibi+ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan, àmọ́, ó fi orí sọlẹ̀, ikùn rẹ̀ bẹ́,* gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú síta.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́