31 Ìgbà náà ni Básíláì+ ọmọ Gílíádì wá láti Rógélímù sí Jọ́dánì, kí ó lè sin ọba dé Jọ́dánì. 32 Básíláì ti darúgbó gan-an, ẹni ọgọ́rin (80) ọdún ni, ó pèsè oúnjẹ fún ọba nígbà tó ń gbé ní Máhánáímù,+ torí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
7 “Àmọ́ kí o fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ọmọ Básíláì+ ọmọ Gílíádì, kí wọ́n sì wà lára àwọn tí á máa jẹun lórí tábìlì rẹ, nítorí bí wọ́n ṣe dúró tì mí+ nìyẹn nígbà tí mo sá lọ nítorí Ábúsálómù+ ẹ̀gbọ́n rẹ.